YORUBA LESSON NOTE – ÀTE̩ ÀKÓÓNÚ IS̩É̩ FÚN SÁÀ ÈTÒ È̩KÓ̩ YÌÍ 2ND TERM
YORUBA LESSON NOTE – ÀTE̩ ÀKÓÓNÚ IS̩É̩ FÚN SÁÀ ÈTÒ È̩KÓ̩ YÌÍ 2ND TERM
Ò̩SÈ̩ ORÍ-Ò̩RÒ̩
1, Èdè: Àtúnyèwò is̩é̩ sáà tó ko̩ já
Às̩à: Àtúnyèwò is̩é̩ sáà tó ko̩ já
Lítírés̩ò̩: Àtúnyèwò is̩é̩ sáà tó ko̩ já
2, Èdè: Àròko̩ ató̩nisó̩nà Alápèjúwe
Às̩à: Oge s̩ís̩e
Lítírés̩ò̩: Orin ìbílè̩ tí ó je̩ mó̩ às̩à ìgbéyàwó
3, Èdè: Oríkì àti è̩yà gbólóhùn
Às̩à: Ò̩nà tí à ń gbà s̩oge
Lítírés̩ò̩: Ìwé kíkà
4, Èdè: Àròko̩ ató̩nisó̩nà Oníròyìn
Às̩à Oyè jíje̩
Lítírés̩ò̩: Ìwé Kíkà – o̩ló̩rò̩ geere
5, Èdè: Is̩é̩ ò̩rò̩-orúko̩ àti ò̩rò̩-aró̩pò-afarajórúko̩
À́s̩à Is̩é̩ abínibí nílè̩ Yorùbá
Lítírés̩ò̩: Lítírés̩ò̩ alohùn tó je̩ mó̩ è̩sìn ìbílè̩
6, Èdè Òǹkà èdè Yorùbá (101 – 200)
Às̩à Ìs̩é̩ Abínibí ilè̩ Yorùbá
Lítírés̩ò̩ Ìwé kíkà
7, Èdè Ìdánwò Àárín sáà
Às̩à Àbè̩wò sílé-ìwé
Lítírés̩ò̩ Àbè̩wò sílé-ìwé
8, Èdè Ò̩rò̩-àpèjúwe àti ò̩rò̩-àpó̩nlé,
Às̩à Àfiwé oge s̩ís̩e ayé-àtijó̩ àti òde-òní
Lítírés̩ò̩ Ìwé kíkà
9, Èdè Àmì ohùn lórí ò̩rò̩ Yorùbá
Às̩à Orin ìbílè̩ tí ó je̩mó̩ is̩é̩ àgbè̩
LÍtírés̩ò̩ Ìwé Kíkà
10, Èdè Is̩é̩ ò̩rò̩-àpèjúwe àti ò̩rò̩-àpó̩nlé
Às̩à Às̩à ìgbéyàwó
Lítírés̩ò̩ Ìwé kíkà
11 Àtúnyè̩wò è̩kó̩
12 Àtúnyè̩wò è̩kó̩
13 Ìdánwò
YORUBA LESSON NOTE – ÀTE̩ ÀKÓÓNÚ IS̩É̩ FÚN SÁÀ ÈTÒ È̩KÓ̩ YÌÍ 2ND TERM
ÀKO̩SÍLÈ̩ IS̩É̩ FÚN Ò̩SÈ̩ KÌN-ÍN-NÍ
Is̩é̩ Yorùbá
Kíláàsì JS 1
Déètì 6-10/01/2025
Àkókò Ìdánilé̩kò̩ó̩ kì-iń-ní
Ìsò̩rí Is̩é̩ Èdè
Orí-ò̩rò̩ Àtúnyè̩wò is̩é̩ sáà tó ko̩já.
Èròńgbà Ìdánilé̩kò̩ó̩ Nígbà tí ìdánilé̩kò̩ó̩ bá ń lo̩ ló̩wó̩, aké̩kò̩ó̩ yóò lè:
- So̩ ohun tí gbólóhùn jé̩.
- Tó̩ka sí àwo̩n è̩yà gbólóhùn tó wà.
- S̩e àpe̩e̩re̩ orís̩irís̩i gbólóhùn.
Kókó Ò̩rò̩ Inú È̩kó̩ olùwà, àbò̩, olórí, àfarahé̩, àpólà, gbólóhùn.
Ohun èlò amús̩é̩yéni Àte̩ ò̩rò̩ orís̩i gbólóhùn. Káàdì pélébé
àti ìwé-ìtó̩kasí pélébé tó s̩e àfihàn ìhun ò̩rò̩.
Ko̩ èdè àmúlò. È̩kó̩ Èdè Yorùbá titun, Oyèbámijí et al.
Àkóónú Gbólóhùn ni ìso̩ tó ní ìtumò̩ kíkún tó sì ní is̩é̩ tó ń jé̩. Irú ìso̩
yìí lè jé e̩yo̩ ò̩rò̩ kan s̩os̩o péré tàbí kí ó jé̩ ìhun pò̩ ò̩rò̩. Bí
àpe̩e̩re̩;
- Olú ra mó̩tò̩.
- Mo yó.
- Ilé tí bàbá kó̩ dára.
- Mojí ti lo̩ sí ilé-ìwé.
- Bádé je̩ è̩bà.
Gbólóhùn gbó̩dò̩ ní ò̩rò̩-ìs̩e kan ó kérétán.
Ìmò̩ àtè̩yìnwá
i). Àkórí Is̩é̩ Kí ni gbólóhùn?
Dárúko̩ orís̩irís̩i gbólóhùn tó wà
ii). Ìrírí aké̩kò̩ó̩ Tó̩ka sí àwo̩n è̩yà gbólóhùn.
O̩gbó̩n ìkó̩ni / àgbékalè̩ is̩é̩ Aké̩kò̩ó̩ sí aké̩kò̩ó̩
Ní s̩ís̩è̩-n-tè̩lé Aké̩kò̩ó̩ sí olùkò̩ó̩
Olùkó̩ sí aké̩kò̩ó̩
Ríronúpò̩, jíjíròròpò̩, píparapò̩ s̩is̩é̩, pínpín àwo̩n aké̩kò̩ó̩ sí
ò̩wò̩ò̩wó̩
- Olùkó̩ yóò bèrè ìbéèrè lórí ìdánilé̩kò̩ó̩ tí ó ko̩já.
- Olùkó̩ yóò s̩e ìfáàrà sí ìdánilé̩kò̩ó̩.
- Olùkó̩ yóò pín àwo̩n aké̩kò̩ó̩ sí ò̩wò̩ò̩wó̩.
- Olùkó̩ yóò fún as̩ojú ò̩wò̩ò̩wó̩ kò̩ò̩kan láàyè láti so̩ èrò wo̩n lórí orí-ò̩rò̩.
- Olùkó̩ yóò s̩e àlàyé kíkún lórí orí-ò̩rò̩.
- Olùkó̩ yóò fún àwo̩n aké̩kò̩ó̩ láàyè láti bèrè ìbéèrè.
Àso̩kágbá – Olùkó̩ yóò ye̩ àko̩sílè àwo̩n aké̩kò̩ó̩ wò, yóò
s̩e àtúns̩e tí ó ye̩ kí ó tó fo̩wó̩ sí i.
Ìgbéléwò̩n Kí ni awé̩-gbólóhùn?
Tó̩ka sí àwo̩n orís̩i awé̩-gbólóhùn tó wà lédè Yorùbá?
Is̩é̩ àmúrelé Dárúko̩ àwo̩n òrìs̩à ilè̩ Yorùbá tí o mò̩.
ÌDÁNILÉ̩KÒ̩Ó̩ KEJÌ
Àkókò Ìdánilé̩kò̩ó̩ kejì
Ìsò̩rí Is̩é̩ Às̩à
Orí-ò̩rò̩ Oge s̩ís̩e
Èròńgbà Ìdánilé̩kò̩ó̩ Nígbà tí ìdánilé̩kò̩ó̩ bá ń lo̩ ló̩wó̩, aké̩kò̩ó̩ yóò lè:
- So̩ àwo̩n ò̩nà tí àwo̩n Yorùbá ń gbà s̩oge.
- S̩àlàyé ohun tí oge s̩ís̩e jé̩ láàárín àwo̩n Yorùbá.
Kókó Ò̩rò̩ Inú È̩kó̩ oge, afínjú, ò̩bùn.
Ohun èlò amús̩é̩yéni Àwòrán àwo̩n tí wó̩n ohun èlò oge s̩ís̩e
àti ìwé-ìtó̩kasí ní Ilè̩ Yorùbá. Àko̩sílè̩ lórí káàdì
Ìwé às̩à àti òrìs̩à ilè̩ Yorùbá.
Dáramólá àti Jé̩jé̩. È̩kó̩ Èdè Yorùbá titun, Oyèbámiji et al
Àkóónú Afínjú ni àwo̩n Yorùbá, wó̩n fé̩ràn láti máa s̩oge, wo̩n korira
ìwà ò̩bun. Onírúurú ò̩nà ló wà tí àwo̩n Yorùbá ń gbà s̩oge
Ìmò̩ àtè̩yìnwá
- Àkórí Is̩é̩ Kí ni oge?
Àwo̩n ò̩nà wo ni Yorùbá máa ń gbà s̩oge?
- Ìrírí aké̩kò̩ó̩ Kí ni ìrírí re̩ nípa oge?
O̩gbó̩n ìkó̩ni / àgbékalè̩ is̩é̩ Aké̩kò̩ó̩ sí aké̩kò̩ó̩
Ní s̩ís̩è̩-n-tè̩lé Aké̩kò̩ó̩ sí olùkò̩ó̩
Olùkó̩ sí aké̩kò̩ó̩
Ríronúpò̩, jíjíròròpò̩, píparapò̩ s̩is̩é̩, pínpín
àwo̩n aké̩kò̩ó̩ sí ò̩wò̩ò̩wó̩
- Olùkó̩ yóò bèrè ìbéèrè lórí ìdánilé̩kò̩ó̩ tí ó ko̩já.
- Olùkó̩ yóò s̩e ìfáàrà sí ìdánilé̩kò̩ó̩.
- Olùkó̩ yóò pín àwo̩n aké̩kò̩ó̩ sí ò̩wò̩ò̩wó̩.
- Olùkó̩ yóò fún as̩ojú ò̩wò̩ò̩wó̩ kò̩ò̩kan láàyè láti so̩ èrò wo̩n lórí orí-ò̩rò̩.
- Olùkó̩ yóò s̩e àlàyé kíkún lórí orí-ò̩rò̩.
- Olùkó̩ yóò fún àwo̩n aké̩kò̩ó̩ láàyè láti bèrè ìbéèrè.
Àso̩kágbá Olùkó̩ yóò ye̩ àko̩sílè àwo̩n aké̩kò̩ó̩ wò, yóò s̩e
àtúns̩e tí ó ye̩ kí ó tó fo̩wó̩ sí i.
Ìgbéléwò̩n Àwo̩n ò̩nà wo ni à ń gbà s̩oge?
Tó̩ka sí orís̩I ò̩nà tí à ń gbà s̩oge?
Is̩é̩ àmúrelé Kí ni àwo̩n ìgbésè̩ ìgbéyàwó?
ÌDÁNILÉ̩KÒ̩Ó̩ KE̩TA
Àkókò Ìdánilé̩kò̩ó̩ ke̩ta
Ìsò̩rí Is̩é̩ Lítírés̩ò̩
Orí-ò̩rò̩ Orin ìbílè̩ tí ó je̩ mó̩ às̩à ìgbéyàwó
Èròńgbà Ìdánilé̩kò̩ó̩ Nígbà tí ìdánilé̩kò̩ó̩ bá ń lo̩ ló̩wó̩, aké̩kò̩ó̩ yóò lè:
- So̩ ní s̩ókí nípa aye̩ye̩ ìgbéyàwó.
- Ko̩ àwo̩n orin ìgbéyàwó .
Kókó Ò̩rò̩ Inú È̩kó̩ e̩kún ìyàwò, ìbálé, Dàdàkúàdà.
Ohun èlò amús̩é̩yéni Fó̩nrán tó s̩e àfihàn orin etíye̩rí.
àti ìwé-ìtó̩kasí Fíìmù tó s̩e àfihàn orin etíye̩rí.. Ìwé E̩kó̩ Èdè Yorùbá Titun,
Oyèbámijí et al.
Àkóónú Ò̩kan-ò-jò̩kan orin ló wà tí àwo̩n Yorùbá máa ń ko̩ níbi
ìgbéyàwó. Orin kíko̩ yìí kò yo̩ ìyàwó tó ń lo̩lé o̩ko̩ alára sílè̩.
Ò̩pò̩ àwo̩n orin bé̩è̩ máa jé̩ ò̩nà̩ láti palè̩ ìyàwó mó̩ fún ìgbé
ayé titun tó fé̩ lo̩ bè̩rè̩. Ìlù àti ìjó máa ń kún orin náà láti dá
àwo̩n ènìyàn lára yá.
Ìmò̩ àtè̩yìnwá
- Àkórí Is̩é̩ Kí ni lítírés̩ò̩?
Tó̩ka sí àwo̩n orís̩irís̩i orin ìbílè̩ Yorùbá.
- Ìrírí aké̩kò̩ó̩ Tó̩ka sí àwo̩n às̩à inú orin ìgbéyàwó.
O̩gbó̩n ìkó̩ni / àgbékalè̩ is̩é̩ Aké̩kò̩ó̩ sí aké̩kò̩ó̩
Ní s̩ís̩è̩-n-tè̩lé Aké̩kò̩ó̩ sí olùkò̩ó̩
Olùkó̩ sí aké̩kò̩ó̩
Ríronúpò̩, jíjíròròpò̩, píparapò̩ s̩is̩é̩, pínpín
àwo̩n aké̩kò̩ó̩ sí ò̩wò̩ò̩wó̩
- Olùkó̩ yóò bèrè ìbéèrè lórí ìdánilé̩kò̩ó̩ tí ó ko̩já.
- Olùkó̩ yóò s̩e ìfáàrà sí ìdánilé̩kò̩ó̩.
- Olùkó̩ yóò pín àwo̩n aké̩kò̩ó̩ sí ò̩wò̩ò̩wó̩.
- Olùkó̩ yóò fún as̩ojú ò̩wò̩ò̩wó̩ kò̩ò̩kan láàyè láti so̩ èrò wo̩n lórí orí-ò̩rò̩.
- Olùkó̩ yóò s̩e àlàyé kíkún lórí orí-ò̩rò̩.
- Olùkó̩ yóò fún àwo̩n aké̩kò̩ó̩ láàyè láti bèrè ìbéèrè.
Àso̩kágbá Olùkó̩ yóò ye̩ àko̩sílè àwo̩n aké̩kò̩ó̩ wò, yóò s̩e àtúns̩e tí ó ye̩ kí
ó tó fo̩wó̩ sí i.
Ìgbéléwò̩n Kí ni lítírés̩ò̩?
Tó̩ka sí àwo̩n Àkóónú orin etíye̩rí.
Is̩é̩ àmúrelé So̩ orís̩irís̩i àwo̩n è̩yà gbólóhùn to mò̩.